21
Àwọn ará Gibeoni gba ẹ̀san
Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, “Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”
Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn, Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda. Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”
Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.”
Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”
Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.”
Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”
Síso Àwọn Ènìyàn Saulu Méje Rọ̀
Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu. Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle.
10 Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru. 11 A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi. 12 Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa. 13 Ó sì mú egungun Saulu àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.
14 Wọ́n sì sin egungun Saulu àti ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ní ilé Benjamini, ní Ṣela, nínú ibojì Kiṣi baba rẹ̀, wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ, lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.
Ìṣẹ́gun lórí Filistini
15 Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi. 16 Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. 17 Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.”
18  1Ki 20.4-8.Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa.
19 Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ.
20 Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa. 21 Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á.
22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

21:18 1Ki 20.4-8.