18
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Kuṣi
Sf 2.12.Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,
ní àwọn ipadò Kuṣi,
tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun
lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.
 
Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,
sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,
sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,
tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
 
Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,
tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,
nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,
ẹ ó rí i,
nígbà tí a bá fun fèrè kan
ẹ ó gbọ́ ọ.
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré
láti ibùgbé e mi wá,
gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,
gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀,
nígbà tí ìrudí bá kún,
nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n.
Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun,
yóò sì mu kúrò,
yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá
àti fún àwọn ẹranko búburú;
àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn
àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.
Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun
láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀,
láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,
ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—
a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.

18:1 Sf 2.12.