24
Ìparun Olúwa lórí ilẹ̀ ayé
1 Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun
gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé
yóò sì pa á run
òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́
yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
2 bákan náà ni yóò sì rí
fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,
fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,
fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin,
fún olùtà àti olùrà,
fún ayáni àti atọrọ
fún ayánilówó àti onígbèsè.
3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá
a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run.
Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá,
ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,
àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
5 àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
wọ́n ti pa àwọn òfin run
wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
8 If 18.22.Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
9 Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10 Ìlú tí a run ti dahoro,
ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
tí a kórè èso tán.
14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
ọláńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun.
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
“Ògo ni fún olódodo n nì.”
Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
“Ègbé ni fún mi!
Alárékérekè dalẹ̀!
Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
yóò ṣubú sínú ihò,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.
Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́
ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
21 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà
gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.