28
Ègbé ni fún Efraimu
Ègbé ni fún adé ìgbéraga,
fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú
àti sí ìlú náà
ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.
Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,
gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,
òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,
yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè
bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,
òun a sì mì ín.
 
Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
yóò jẹ́ adé tí ó lógo,
àti adé tí ó lẹ́wà
fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo
fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́
àti orísun agbára
fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.
 
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì
wọ́n pòòrì fún ọtí líle,
àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle
wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì
wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,
wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,
wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì
kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
 
“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?
Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?
Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,
sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí,
ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
 
11  1Kọ 14.21.Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀
Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
12  Mt 11.29.àwọn tí ó sọ fún wí pé,
“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;
àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”;
ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé,
ṣe èyí, ṣe ìyẹn,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,
wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
 
14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
kò le kàn wá lára,
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”
16  Ro 9.33; 10.11; 1Pt 2.4-6.Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,
òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;
ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé
kì yóò ní ìfòyà.
17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n
àti òdodo òjé òsùwọ̀n;
yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,
omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí
ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.
18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;
àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.
Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,
a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
19 Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni
yóò máa gbé ọ lọ,
ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,
ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”
 
Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí
yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,
ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
21  Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
ní òkè Perasimu
yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
ní àfonífojì Gibeoni—
láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,
yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.
22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;
Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi
nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
 
23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,
fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.
24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn
yóò ha máa tulẹ̀ títí bi?
Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí
ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?
25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ
òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì
kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?
Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,
barle tí a yàn,
àti spelti ní ipò rẹ̀?
26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà
ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.
 
27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,
bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;
ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,
ọ̀gọ ni a sì lu kummini.
28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;
bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.
Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,
àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.
29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá,
oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

28:11 1Kọ 14.21.

28:12 Mt 11.29.

28:16 Ro 9.33; 10.11; 1Pt 2.4-6.