19
Sakeu agbowó òde
1 Mk 10.46.Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀. 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. 3 Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú. 4 Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.
5 Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.” 6 Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.
7 Lk 5.29-30; 15.1-2.Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”
8 Lk 7.13; 3.14; Ek 22.1; Le 6.5; Nu 5.6-7.Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
9 Lk 3.8; 13.16; Ro 4.16.Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu. 10 Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
Òwe mina mẹ́wàá
11 Lk 9.51; 13.22; 17.11; 18.31; 9.27.Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí. 12 Mt 25.14-30. Mk 13.34.Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13 Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14 “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’
15 “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.
16 “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’
17 Lk 16.10.“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18 “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’
19 “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’
20 “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; 21 nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn, ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22 “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn. 23 Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24 “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mina mẹ́wàá.’
25 “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’
26 Mt 13.12; Mk 4.25; Lk 8.18.“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
Ó wọ ilé pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
28 Mk 10.32.Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 29 Mt 21.1-9; Mk 11.1-10; Jh 12.12-18.Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30 Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”
32 Lk 22.13.Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
34 Lk 7.13.Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”
35 Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. 36 2Ọb 9.13.Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.
37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí,
38 Sm 118.26; Lk 13.35; 2.14.wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
39 Mt 21.15-16; Hb 2.11.Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
41 Lk 13.33-34.Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó síjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42 Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 Lk 21.21-24; 21.6; Isa 29.3; Jr 6.6; El 4.2.Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 1Pt 2.12.Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”
Jesu nínú tẹmpili
45 Mt 21.12-13; Mk 11.15-17; Jh 2.13-17.Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.”
47 Mk 11.18; Lk 21.37; 22.53.Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
19:1 Mk 10.46.
19:7 Lk 5.29-30; 15.1-2.
19:8 Lk 7.13; 3.14; Ek 22.1; Le 6.5; Nu 5.6-7.
19:9 Lk 3.8; 13.16; Ro 4.16.
19:11 Lk 9.51; 13.22; 17.11; 18.31; 9.27.
19:12 Mt 25.14-30.
19:12 Mk 13.34.
19:17 Lk 16.10.
19:26 Mt 13.12; Mk 4.25; Lk 8.18.
19:28 Mk 10.32.
19:29 Mt 21.1-9; Mk 11.1-10; Jh 12.12-18.
19:32 Lk 22.13.
19:34 Lk 7.13.
19:36 2Ọb 9.13.
19:38 Sm 118.26; Lk 13.35; 2.14.
19:39 Mt 21.15-16; Hb 2.11.
19:41 Lk 13.33-34.
19:43 Lk 21.21-24; 21.6; Isa 29.3; Jr 6.6; El 4.2.
19:44 1Pt 2.12.
19:45 Mt 21.12-13; Mk 11.15-17; Jh 2.13-17.
19:47 Mk 11.18; Lk 21.37; 22.53.