7
Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkejì
1 Lk 6.37-38; Mk 4.24; Ro 2.1; 14.10.“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
3 Lk 6.41-42.“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
Béèrè, kànkùn, wá kiri
7 Lk 11.9-13; Mk 11.24; Jh 15.7; 16.23-24; Jk 4.3; 1Jh 3.22; 5.14.“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? 10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? 12 Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.
Ọ̀nà tóóró àti ọnà gbòòrò
13 Lk 13.23-24; Jr 21.8; De 30.19; Jh 14.6; 10.7.“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
Igi àti èso rẹ̀
15 Mt 24.11,24; El 22.27; 1Jh 4.1; Jh 10.12.“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná. 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 Lk 6.46.“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé
24 Lk 6.47-49; Jk 1.22-25.“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
28 Mk 1.22; Lk 4.32; Mt 11.1; 13.53; 19.1; 26.1. Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, 29 nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.
7:1 Lk 6.37-38; Mk 4.24; Ro 2.1; 14.10.
7:3 Lk 6.41-42.
7:7 Lk 11.9-13; Mk 11.24; Jh 15.7; 16.23-24; Jk 4.3; 1Jh 3.22; 5.14.
7:13 Lk 13.23-24; Jr 21.8; De 30.19; Jh 14.6; 10.7.
7:15 Mt 24.11,24; El 22.27; 1Jh 4.1; Jh 10.12.
7:21 Lk 6.46.
7:24 Lk 6.47-49; Jk 1.22-25.
7:28 Mk 1.22; Lk 4.32; Mt 11.1; 13.53; 19.1; 26.1.