3
Ẹ̀rí jíjẹ́ nípa àwọn ọmọ Israẹli
1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:
2 “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn
nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;
nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà
fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”
3 Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀
láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?
4 Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó,
bí kò bá ní ohun ọdẹ?
Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀
bí kò bá rí ohun kan mú?
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀
nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?
Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀
nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
6 Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,
àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?
Tí ewu bá wa lórí ìlú
kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?
láìfi èrò rẹ̀ hàn
fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
8 Kìnnìún ti bú ramúramù
ta ni kì yóò bẹ̀rù?
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀
ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?
9 Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu
àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;
kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀
àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”
10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,
“àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;
yóò wó ibi gíga yín palẹ̀
a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
ní igun ibùsùn wọn
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò
yóò sì wó lulẹ̀.
15 Èmi yóò wó ilé òtútù
lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé
a ó sì pa ilé ńlá náà run,”
ni Olúwa wí.