3
Ìgbàgbọ́ tàbí iṣẹ́ òfin
Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín, nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? Gẹ 15.6; Ro 4.3.Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”
Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. Gẹ 12.3; 18.18; Ap 3.25.Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Ro 4.16.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo.
10  De 27.26.Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n”. 11  Hk 2.4; Ro 1.17; Hb 10.38.Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” 12  Le 18.5; Ro 10.5.Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 13  De 21.23.Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” 14 Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.
Òfin àti ìlérí
15 Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. 16  Gẹ 12.7.Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣọ wí pé, “fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀,” bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, “àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kristi. 17  Ek 12.40.Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀nlénírinwó (430) ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. 18  Ro 11.6.Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí.
19  Ro 5.20.Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. 20 Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.
21  Ro 8.2-4.Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. 22  Ro 3.9-19; 11.32.Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.
Ọmọ Ọlọ́run
23 Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24 Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.
26 Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27 Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 28  Ro 10.12.Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29 Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

3:6 Gẹ 15.6; Ro 4.3.

3:8 Gẹ 12.3; 18.18; Ap 3.25.

3:9 Ro 4.16.

3:10 De 27.26.

3:11 Hk 2.4; Ro 1.17; Hb 10.38.

3:12 Le 18.5; Ro 10.5.

3:13 De 21.23.

3:16 Gẹ 12.7.

3:17 Ek 12.40.

3:18 Ro 11.6.

3:19 Ro 5.20.

3:21 Ro 8.2-4.

3:22 Ro 3.9-19; 11.32.

3:28 Ro 10.12.