32
Ọ̀rọ̀ Elihu
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀. Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.
Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé,
“Ọmọdé ni èmi,
àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
 
10 “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
11 Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;
èmi fetísí àròyé yín,
nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;
12 àní, mo fiyèsí yín tinútinú.
Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;
tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
13 Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí;
Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
14 Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
 
15 “Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́,
wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16 Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́;
wọn kò sì dáhùn mọ́.
17 Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi,
èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
18 Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,
ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
19 Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò;
ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
20 Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,
èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
21 Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan,
bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
22 Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀,
ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.